Hymn 110: All ye the holy saints of God

Enyin enia Olorun

  1. f Ẹnyin enia Ọlọrun,
    Okunkun yi aiye ka;
    Sọ ihin ayọ̀ ti Jesu
    Ni gbogb’ orilẹ-ede;
    Ihin ayọ̀, Ihin ayọ̀
    Ti ‘toye Olugbala.

  2. mf Má tiju Ihinrere Rẹ̀,
    Agbara Ọlọrun ni.
    N’ ilu t’a kò wasu Jesu,
    Kede ‘dasilẹ f’ ondè;
    Idasilẹ, Idasilẹ
    Bi t’ awọn ọmọ Sion.

  3. B’ aiye on Eṣu dìmọlu
    S’ iṣẹ Olugbala wa,
    Ja fun iṣẹ Rẹ̀, má fòya,
    Màṣe bẹ̀ru enia.
    Nwọn nṣe lasan, Nwọn nṣe lasan,
    Iṣẹ Rẹ̀ kò le bajẹ.

  4. p ‘Gbat’ ewu nla ba de si nyin,
    Jesu y’o dabobo nyin;
    Larin ọta at’alejo,
    f Jesu y’o jẹ Ọrẹ́ nyin;
    Itọju Rẹ̀, Itọju Rẹ̀
    Y’ o pẹlu nyin tit’ opin. Amin.