- f Larin ijọ Kristian
Jẹ k’ ifẹ wà yika;
Awọn t’ iṣ’ ajumọ̀-jogun
Ti y’o jọ gba ‘bukun.
- K’ ilara, ọm’ èṣu,
Jina si ọdọ wa;
Ki awọn ti ngbọ t’ Olulwa,
Wà n’ ifẹ t’ o daju.
- Bayi n’ Ijọ t’ ihin
Y’o farawe t’ okè,
Nibi iṣàn ifẹ gbe wà
Ifẹ l’ ọkan gbogbo. Amin.