f Gbọ ! orin ti Jubeli, O dabi sisán ará; Tabi bi kikún okun Gbat’ igbì rẹ̀ ba nlù ‘lẹ ff Halleluia! Ọlọrun Olodumare jọba; ff Halleluia ! k’ ọ̀rọ na Dún yi gbogbo aiye kà.
f Halleluia !—gbọ iró, Lati aiye de ọrun, Nji orin gbogbo ẹda, L’oke, nisalẹ, yika, Wo, Jehofa ti ẹtẹ̀ p Ida w’akọ̀; -- o paṣẹ, Awọn ijọba aiye Di ijọba Ọmọ Rẹ̀.
Y’o jọba yi aiye ka, Pẹlu agbara nlanla; Y’o jọba ‘gbati ọrun, At’ aiye ba kọja lọ; p Opin de: lab’ ọpa Rẹ̀. pp L’ọtan enia ṣubu: ff Halleluia ! Ọlọrun Ni gbogbo l’ohun gbogbo. Amin.