- f Ji, apa Ọlọrun, k’ o ji,
Gbe ‘pa Rẹ wọ̀, mì orilẹ̀;
Ni sisin Rẹ, jẹ k’ aiye ri
Iṣẹgun iṣẹ anu Rẹ.
- T’ itẹ Rẹ wi fun keferi,
“Emi Jehofah Ọlọrun.”
Ohùn Rẹ y’o d’ere wọn ru
Yio wo pẹpẹ wọn lulẹ̀.
- mf Má jẹ k’ a ta ‘jẹ́ silẹ mọ́,
Ẹbọ asan fun enia;
Si ọkàn gbogbo ni k’ lò
Ẹjẹ t’o tiha Jesu yọ.
- f Olodumare, n’ apa Rẹ
F’ opin s’ itanjẹ Imale:
J’ ẹ̀wọn isin èke Popu,
Dà ‘binu agberaga ro.
- mf Ki ‘gbojurere Sion de,
K’ a m’ẹyà Israel wá ‘le;
N’ iyanu k’a f’oju wa ri
Keferi, Ju, l’agbo Jesu.
- f Olodumare, lọ́ ‘fẹ Rẹ,
L’ororukọ, ilẹ gbogbo;
Ki gbogb’ ọta wolẹ fun Ọ.
Ki nwọn gba Jesu l’ Oluwa. Amin.