mf Lat’ oke tutu Grinland, Lati okun India, Nib’ odo orùn Afrik, Nṣan yanrin wura wọn: Lat’ ọpọ odo gbani Lati igbẹ ọpẹ Nwọn npè wa k’a gba ‘lẹ wọn, L’ẹwọ̀n iṣina wọn.
Afẹfẹ orùn didun, Nfẹ jẹjẹ ni Seilon; Bi ohun t’a nri dara di Enia l’o buru: mp Lasan lasan lỌlọrun Nt’ ẹbùn Rẹ̀ gbogbo ka, p Keferi, ni ‘fọju wọn. Nwolẹ bọ okuta.
mp Njẹ awa ti a mòye Nipa ọgbọn ọrun, O tọ ka f’ imọlẹ du Awọn t’ o wà l’ okùn? ff Igbala, A, Igbala ! Fọnrere ayọ na Titi gbogbo orilẹ Yio mọ̀ Messia.
f Ẹfufu, mu ‘hin rẹ lọ, Ati ẹnyin odo’ cr Titi, bi okun ogo Y’o tàn yi aiye ka; Tit’ Ọdagutan f’ a pa Fun irapada wa ff Yio pada wà jọba, L’ alafia lailai. Amin.