- mf A gboju soke si Ọ,
At’ọwọ, ati ọkan;
Tẹwọgba adura wa,
p B’ o tilẹ ṣe ailera.
- Oluwa jẹ k’a mọ̀ Ọ,
Jẹ k’a mọ orukọ Rẹ;
Jẹ k’ awa ṣe ifẹ Rẹ,
Bi nwọn ti nṣe li ọrun.
- mp Nigbati a sùn l`oru,
Ṣọ́ wa, k’o duro tì wa;
f Nigbati ilẹ si mọ́,
ff K’a ji, k’a f’iyìn fun Ọ. Amin.