- f Iyin f’Ẹni Mimọ julọ,
Loke ati n’ilẹ;
Ọrọ Rẹ̀ gbogbo je iyanu,
Gbogb’ ọna Rẹ̀ daju/
- mf Ọgbọn Ọlọrun ti pọ to!
p Gbat’enia ṣubu;
cr Adam keji wá s’oju ‘ja,
f Ati lati gbàla.
- mf Ọgbọn ifẹ! P’ẹran ara
p T’ o gbe Adam ṣubu,
cr Tun b’ọta ja ija ọtun,
f K’ o jà k’o si ṣẹgun.
- mf Ati p’ẹbùn t’o j’ or’ọfẹ,
Sọ ara di ọtun;
p Ọlọrun papa Tikarẹ̀
J’Ọlọrun ninu wa.
- Ifẹ ‘yanu! Ti Ẹniti
O pa ọta enia,
Ninu àwọ awa enia
Jẹ irora f’enia.
- Nikọkọ ninu ọgba ni,
Ati lori igi,
To si kọ́ wa lati jiya,
To kọ́ wa lati kú.
- f Iyin f’Ẹni Mimọ julọ,
Loke ati n’ile;
Ọrọ Rẹ gbogbo jẹ ‘yanu,
Gbogb’ ọ̀na Rẹ̀ daju. Amin.