Hymn 142: Did Christ o'er sinners weep?

Kristi sun f’ elese

  1. p Kristi sun f’ẹlẹṣẹ,
    Oju wa o gbẹ bi?
    K’omi ‘ronu at’ikanu,
    Tu jade l’oju wa.

  2. p Ọmọ Ọlọrun nsun,
    Angẹli ṣiju wò!
    K’o damu, iwọ ọkàn mi,
    O d’omi ni fun ọ.

  3. p O sun k’awa k’o sun,
    Ẹṣẹ bère ẹkun:
    Ọrun nikan ni kò s’ ẹ̀ṣẹ,
    Nibẹ ni kò s’ ẹkun. Amin.