- mf Iwọ lọw’ ẹnit’ ire nṣàn,
Mo gb’ ọkan mi si Ọ;
di N’ ibanujẹ at’ iṣẹ́ mi,
p Oluwa, ranti mi.
- mp ‘Gba mo nkerora l’ọkàn mi,
T’ẹṣẹ wọ̀ mi lọrùn:
cr Dari gbogbo ẹ̀ṣẹ ji mi,
p Ni ifẹ ranti mi.
- mp Gba ‘danwo kikan yi mi ka,
Ti ibi lé mi bá;
cr Oluwa, fun mi l’agbara,
p Fun rere, ranti mi.
- mp Bi ‘tiju at’ ẹgàn ba dé,
‘Tori Orukọ Rẹ;
mf Ngo yọ̀ s’ẹgàn, ngo gbà ‘tiju,
B’ iwọ ba ranti mi.
- di Oluwa, ‘gba ikú ba de,
Em’ o sa kú dandan;
p K’ eyi j’ adura gbẹhin mi,
Oluwa, ranti mi. Amin.