Hymn 15: Abide with me! fast falls the eventide;

Wa ba mi gbe ! ale fere le tan

  1. mf Wà ba mi gbe! alẹ fẹrẹ lẹ tan,
    Okuukun nṣú; Oluwa ba mi gbe,
    Bi oluranlọwọ miran ba yẹ̀,
    Iranwọ alaini, wà ba mi gbe!

  2. p Ọjo aiye mi nsare lọ s’opin,
    Ayọ aiye nkú, ogo rẹ̀ nwọmi;
    Ayida at’ ibajẹ ni mo nri;
    cr ‘Wọ ti ki yipada wá ba mi gbe.

  3. mp Má wá l’ẹrù b’Ọba awọn ọba,
    Ṣugbọn ki o ma bọ̀ b’oninure;
    Ki o si ma kanu fun ègbé mi;
    Wa, Ọrẹ eleṣe, wa ba mi gbe.

  4. Mo nfẹ Ọ ri, ni wakati gbogbo:
    Ki l’o le ṣẹgun Eṣu b’ore Rẹ?
    Tal’ o le ṣe amọna mi bi Rẹ?
    N’nu ‘banujẹ at’ ayọ, ba bi gbe!

  5. mf Pẹlu ‘bukun Rẹ, ẹ̀ru ko ba mi:
    Ibi kò wuwo, ẹkún kò korò;
    f Oró ikú da? ‘ṣegun isà da?
    Ngo ṣẹgun sibẹ, b’ Iwọ ba mi gbe.

  6. p Wa ba mi gbe ni wakati iku,
    cr Ṣe ‘mọlẹ mi, si tọka si ọrun:
    f B’ aiye ti nkọja, k’ ilẹ ọrun mọ,
    Ni yiyè, ni kiku, wà ba mi gbe. Amin.