- mf Oluwa, b’ agbowode nì,
Mo gb’ọkàn mi le Ọ;
Oluwa, f’ ore-ọfẹ wi,
p K’ o ṣe anu fun mi.
- mf Mo lù aiduro aiya mi,
p Ẹkun at’irora;
K’ o gb’ ọkàn mi ‘nu irora,
p K’ o ṣe anu fun mi.
- N’itiju mo jẹw` ẹṣẹ mi,
Jọ fun mi n’ ireti;
Mo bè, ‘tori ẹjẹ Jesu,
p K’ o ṣe anu fun mi.
- Olori ẹlẹṣẹ ni mi,
Ẹṣẹ mì papọju;
Nitori ikú Jesu wa,
p K’ o ṣe anu fun mi.
- Mo duro ti agbelebu
Nkò sa f’ ojiji rẹ̀;
Ti Ọlọrun t’ o pọ l’ anu,
p O ti ṣanu fun mi. Amin.