Hymn 176: Sinners, turn: why will you die?

Elese, e yipada

  1. mp Ẹlẹṣẹ, ẹ yipada,
    Eṣe ti ẹ o fi ku?
    Ẹlẹda nyin ni mbere,
    T’ o fẹ ki ẹ ba On gbe;
    Ọràn nla ni o mbi nyin,
    Iṣẹ ọwọ Rẹ̀ ni nyin.
    cr A! enyin alailọpọ,
    Eṣe t’ ẹ o kọ̀ ‘fẹ́ Rẹ?

  2. p Ẹlẹṣẹ, ẹ yipada,
    Eṣe ti ẹ o fi ku?
    Olugbala ni mbere,
    Ẹnit’ o ngb’ ẹmi nyin là;
    Iku Rẹ̀ y’o jasan bi?
    Ẹ o tun kan mọ ‘gi bi?
    di Ẹni ‘rapada, eṣe
    Ti ẹ o gàn ore Rẹ̀?

  3. p Ẹlẹṣẹ, ẹ yipada,
    Eṣe ti ẹ o fi ku?
    Ẹmi mimọ ni mbere,
    Ti nf’ọjọ gbogbo rọ̀ nyin;
    Ẹ kì o ha gb’ore Rẹ̀?
    Ẹ o kọ̀ iye sibẹ?
    di A ti nwa nyin pẹ, eṣe
    T’ẹ mbi Ọlọrun ninu?

  4. cr Iyemeji ha nṣe nyin
    Pe, ifẹ ni Ọlọrun,
    Ẹ kì o ha gb’ ọrọ Re?
    K’ ẹ gbà ileri Rẹ̀ gbọ?
    p W’ Oluwa nyin lọdọ nyin,
    pp Jesu nsun: w’omije Rẹ̀;
    Ẹjẹ Rẹ̀ pẹlu nke, pe,
    “Eṣe ti e o fi ku?” Amin.