- mp Baba alanu t’o fẹ wa,
Mo gb’ọkàn mi si Ọ;
mf Ipá Rẹ t’ o pọ̀ l’ o gbà wa;
Awa nkọrin si Ọ.
- f Tirẹ papa l’ awa fẹ ṣe,
Gb’ ọkán wa fun ẹbọ;
O da wa, o si tun wa bi,
A f’ ara wa fun Ọ.
- Ẹmi Mimọ́, wá sọdọ mi,
F’ ifẹ Oluwa hàn;
Fun mi k’emi k’o lè ma rìn,
N’ ifẹ Oluwa mi. Amin.