mp A! Jesu, Iwọ nduro, Lode, lẹhin ‘lẹkun; Iwọ fi suru duro, Lati kọja sile; cr ‘Tiju ni fun wa, Kristian, Awa ti nj’ okọ Rà! Itiju gidigidi, p B’a ba jọ Rẹ̀ sode.
mf A! Jesu, Iwọ nkànkun, Ọwọ na si l’ àpá; Ẹgun yi ori Rẹ ka, Ẹkun b’ oju Rẹ jẹ: cr A! ifẹ ‘yanu l’ eyi, T’o nfi suru duro! di A! ẹ̀ṣẹ ti kò l’ ẹgbẹ, T’o há ‘lẹkun pinpin!
p A! Jesu, Iwọ mbẹbẹ L’ ohùn pẹlẹpẹlẹ, pp “Mo ku f’ẹnyin ọmọ mi Bayi l’ ẹ ṣe mi si?” mf Oluwa, a ṣilẹkun N’ ikanu on ‘tiju! cr Olugbala, wá wọle Má fi wa silẹ lọ. Amin