ITAN ORI AGBELEBU
GETSEMANE.
- p N’ ìwaiya ‘jakadi, | On nikan njà,
O nfẹ iranlọwọ, | ṣugbọn kò ri.
- B’ oṣupa ti nwọ̀ | lor’ òke Olif’,
Adura tani ngòke | loru yi?
- Ẹjẹ wo l’ eyi ti | nrọ̀ bi ojo
Lat’ ọkàn Rẹ wá, “Ẹ|ni ‘banujẹ?”
- Irora aileso | mbẹ loju Rẹ,
Ojiya ti mbẹ̀bẹ̀, | tan’ Iwọ?
ỌNA IKANU.
- mp Gbọ b’ O ti mba ọ sọ̀|rọ lọkàn re,
“Ọmọ ti mo ku fun, | tẹle mi.
- “Ki nmá m’ ago ti | Baba fun mi bi|
‘Gbati mimu rẹ̀ jẹ | ‘gbala rẹ?
- “ A lu, a tutọ si, | a fi ṣẹ̀fẹ,
A na, a sì de | l’ ade ẹ̀gún.
- “ Mo nlọ si Golgota, | nibẹ ngo ku,
cr ‘Tor’ ifẹ mi si Ọ; | Emi ni.”
ỌRỌ MEJE LORI AGBELEBU.
- mp A kan mọ ‘gi ẹ̀sin. | kò kerora,
O r’ẹrù ẹṣẹ wa, | Tirẹ̀ ko.
- Wọ Orùn mi, o le | wọ̀ okùn bi?
Ọrọ wo l’o nte|nu Rẹ wá ni?
- “Baba dariji wọn,” | l’adura Rẹ̀
cr Baba si gbọ, bi | ‘ti ma gbọ́ ri.
- Gbọ bi olè nì ti | ntọrọ anu,
mf On ṣe ‘leri Pa|radise fun.
- Ibatan at’Ọrẹ | rọ̀gba yika,
Maria on Magdalen | r’opin rẹ̀.
- Meji ninu wọn di | tiyátọmọ;
Ọkàn t’ọ̀rọ Rẹ̀ | ti sọ d’ọkan.
- p Okunkun bò ilẹ, | ọ̀sán d’oru,
Iṣẹju kọja b’ | ọdun pipọ.
- pp Gbọ́ ‘gbe ‘rora lat’ i|nu okùn na,
“Baba, ‘Wọ kọ̀ mi | silẹ, eṣe?”
- A| ikọsilẹ nla | | iku ègún|
Igbe kil’ eyi, | :Ongbẹ ngbẹ mi.”
- cr Gbọ́, “O ti pari,” | Ijakadi pin,
Iku at ipoku, | a ṣẹ́ wọn.
- p Baba, gbà ẹmi mi,” | l’o wi kẹhin,
Krist’ Oluwa iye, | O si ku.
IKESI.
- mp “Ọmọ ‘rora mi, ti | mo f’ ẹjẹ rà,
Mo gbà ọ lọw’ èṣu, | f’ Ọlọrun;
- cr “Wa alarẹ̀, wá f’ori | l’ aìya mi;
Sapamọ sọdọ mi, | k’ o simi.
- mf “Wá sọdọ Baba mi, | wá l’ aibẹru,
Alagbawi rẹ, | wà nitosi.
- “Wá, mu ninu ore-ọfẹ Ẹmi:
Emi ni ìní rẹ, | ‘Wọ t’ emi.”
IDAHUN.
- mp Mo f’ara mi fun Ọ. | Oluwa mi,
Sa f;fẹe Rẹ ‘yebiye fun mi.
- crGbogb’ ohun ti mo ni, | t’ ara t’ọkàn,
Nkò jẹ fi dù Ọ, | gbà gbogbo rè.
- mf Sa ba mi gbe dopin, | Oluwa mi,
Jesu, Olugbala, | Emmanuel.
- B’ akoko Rẹ ba de, | jẹ ki nyìn Ọ;
Yìn Ọ n’ ile Rẹ | titi lailai. Amin.