- f Lọ sọ fun gbogbo aiye,
cr Lọ tan ihin ayọ̀ yi;
Eti t’ o ba gbọ́, y’o ṣi,
Ọkàn t’ o ba gbọ́, y’o là
- f Jesu Olugbala wa,
T’ a sin, fi boji silẹ̀;
Ọlọrun gba ẹbọ Rẹ̀,
Ẹbọ ẹ̀ṣẹ araiye.
- mf O ji lati má kú mọ,
Akọbi awọn t’ o sùn;
Ẹniti o ba gba gbọ
Yio ye, b’ o tilẹ kú.
- mf Angẹli ! ẹda ọrun,
f Ẹ ba araiye gberin;
Jesu Oludande ji,
Alafia titi lai. Amin.