- ff ALLELUYA ! ALLELUYA ! ALLELUYA !
f Ija d’opin, ogun si tan:
Olugbala jagun molu;
ff Orin ayọ l’a o ma kọ. ---- Alleluya !
- f Gbogbo ipa n’ ikú ti lò;
Ṣugbọn Kristi f’ ogun rẹ̀ ka:
ff Aiye ! ẹ ho iho ayọ̀. --- Alleluya !
- mf Ọjọ mẹta na ti kọja,
cr O jinde kuro nin’ okú:
ff Ẹ f’ ogo fun Oluwa wa. --- Alleluya !
- f O d’ ẹ̀wọn ọrun apadi,
O ṣilẹkùn ọrun silẹ̀;
ff Ẹ kọrin iyin ṣẹgun Rẹ̀.--- Alleluya !
- p Jesu, nipa ìya t’ O jẹ,
mf Gba wa lọwọ oro ikú,
cr K’a le yè, k’asi ma yìn Ọ. ----Alleluya. Amin.