- mf Jesu t’ o kú, k’ o gb’ aiye là,
Jinde kuro ninu okú,
Nipa agbara Rẹ̀;
ff A da silẹ lọwọ ikú,
O d igbekun n’ ìgbekun lọ,
cr O yè, k’ o má kú mọ.
- Ẹnyin ọm’ Ọlọrun, ẹ wò
Olugbala ninu ogo;
O ti ṣẹgun ikú:
Má banujẹ, má bẹ̀ru mọ,
O nlọ pese àye fun nyin,
Yio mu nyin lọ ‘le.
- mf O f’ oju anu at’ ifẹ
Wò awọn ti O rà pada;
Awọn ni ayọ̀ Rẹ̀;
O ri ayọ at’ iṣẹ́ wọn,
O bẹbẹ̀ ki nwọn lè ṣẹgun,
ff Ki nwọn ba jọba lai. Amin.