Hymn 234: Jesus, stand among us

Jesu, wa sarin wa

  1. mf Jesu, wá sarin wa,
    L’ agbar’ ajinde;
    Jẹ k’isìn wa nihin
    Jẹ ìsin ọ̀wọ̀.

  2. mp Mi Ẹmi Mimọ Rẹ,
    Sinu ọkàn wa;
    cr Mu ‘foiya at’ aro
    Kuro l’ọkàn wa.

  3. f Bi a ti nyara lọ,
    Lọna àjo wa;
    K’a ma ṣọna f’orọ̀
    T’ ọj’ aiyeraiye. Amin.