- f “Mo mọ̀ p’Oludande mi mbẹ;”
Itunu nla l’ eyi fun mi !
p cccẸnit’ o ku lẹkan;
f O mbẹ, Ori ìye mi lai.
- f O mbẹ, lati ma bukun mi,
p O si mbẹ̀bẹ fun mi loke;
ff O mbẹ, lati ji mi n’bojì,
Lati gbà mi là titi lai.
- cr O mbẹ, Ọrẹ́ korikosun,
Ti y’o pa mi mọ de opin;
f O mbẹ, emi o ma kọrin;
Woli, Alufa, Ọba mi.
- O mbẹ, lati pèse àye,
Y’o sì mu mi de ‘bẹ layọ̀;
O mbẹ, ogo l’ orukọ Rẹ̀;
Jesu, ọkanna titi lai.
- f O mbẹ, mo bọ́ lọw’ aniyàn;
O mbẹ, mo bọ́ lọwọ ewu;
A! ayọ l’ ọ̀rọ yi fun mi
f “Mo mọ̀ p’ Oludande mi mbẹ.” Amin.