- mf Adaba ọrun, sọkalẹ̀,
Gbe wa lọ l’apa iyẹ Rẹ;
f Ki o si gbe wa ga soke,
Jù gbogbo ohun aiye lọ.
- mf Awa iba lè ri itẹ
Olodumare Baba wa,
p Olugbala joko nibẹ,
O gunwà l’awọ̀ bi tiwa.
- cr Ẹgbẹ mimọ́ duro yi ká,
Itẹ, Agbara wolẹ̀ fun,
Ọlọrun hàn ninu ara,
O si tàn ogo yi wọn ka.
- f Oluwa, akokò wo ni
Emi o de bugbe loke?
T’ emi o ma ba wọn wolẹ̀,
Ki mma sìn Ọ, ki mma kọrin? Amin.