- mf Ẹmi anu, otọ, ifẹ,
Rán agbara Rẹ t’oke wá;
cr Mu iyanu ọjọ oni,
De opin akoko gbogbo.
- f Ki gbogbo orilẹ ede,
Kọ orin ogo Ọlọrun;
Ki a si kọ́ gbogbo aiye,
N’ iṣẹ Olurapada wa.
- mp Olutunu at’ Amọnà
cr Jọba ijọ eni Rẹ,
mf K’ araiye mò ibukun Rẹ,
Ẹmì anu, otọ, ifẹ. Amin.