- mf Ẹmi ọrun, gb’ adura wa,
Wá gbe ‘nu ile yi;
Sọkalẹ̀ pẹl’ agbara Rẹ,
f Wá, Ẹmi Mimọ́, wá.
- mf Wá, bi ‘mọlẹ; si fihàn wa
B’ aini wa ti pọ to:
Wá, tọ́ wa si ọna iye,
Ti olododo nrin.
- Wá, bi iná ẹbọ mimọ́,
S’ ọkàn wa di mimọ́;
Jẹ ki ọkàn wa jẹ ọrẹ,
F’ orukọ Oluwa.
- p Wá bi ìri, si wá bukun
Akoko mimọ́ yi:
cr Ki ọkàn alaileso wa
Lè yọ̀ l’agbara Rẹ.
- p Wà, bi adaba, n’ apa Rẹ:
Apa ifẹ mimọ́;
Wá, jẹ ki ijọ Rẹ l’aiye,
Dabi Ijọ t’ọrun.
- f Ẹmi ọrun, gb’ adura wa,
S’ aiye yi ‘ ile Rẹ;
Sọkalẹ pẹl’ agbara Rẹ,
Wá, Ẹmi Mimọ́, wá. Amin.