Hymn 297: For my sake, and the Gospel's

Tori Mi at’ Ihinrere

  1. f “Tori Mi at’Ihinrere,
    Ẹ lọ sọ t’Iràpada;
    cr Awọn onṣe Rẹ́ nke, ‘Amin’!
    f Tirẹ ni gbogbo ogo;”
    mf Nwọn nsọ t’ibí, t’iya, t’iku,
    Ifẹ etutu nla Rẹ̀;
    Nwọn kà ohun aiye s’ ofò,
    f T’ ajinde on ‘jọba Rẹ̀.

  2. f Gbọ, gbọ ipè ti Jubili,
    O ndun yi gbogb’aiye ka;
    cr N’ilẹ ati loju okun,
    A ntàn ihin igbala,
    p Bi ọjọ na ti nsunmọle,
    T’ Ogun si ngbona janjan,
    f Imọlẹ Ila-orùn na
    ff Y’o mọ́ larin okunkun.

  3. f Siwaju ati siwaju
    Lao ma gbọ Halleluya,
    cr Ijọ ajagun y’o ma yọ̀,
    Pẹl’ awọn oku mimọ;
    A fọ aṣọ wọn n’nu ẹjẹ,
    Duru wura wọn si ndún;
    ff Aiye at’ọrun d’ohùn pọ̀
    Nwọn nkọ orin iṣẹgun.

  4. f O de, Ẹnit’ a nw’ ọna Rẹ̀,
    Ẹni ikẹhin na de,
    Immanuẹli to d’ade,
    Oluwa awọn mimọ,
    cr Iye, Imọlẹ at’Ifẹ,
    Mẹtalọkan titi lai;
    ff Tirẹ ni Itẹ Ọlọrun
    rall Ati t’Ọdọ-agutan. Amin.