mf Nigbat’ imọlẹ owurọ Ba nti ìla orùn tàn wa, A! Orùn ododo mimọ́ Má ṣai fi anu ràn si mi! Tu isudẹ̀dẹ ẹ̀bi ka S’ okunkun mi d’ imọlẹ nla.
mp ‘Gbati mba m’ ẹbọ orọ wá ‘Waju Ọlọrun t’ o logo, Olugbala, ti mba nkanu p Nitori ẹ̀ṣẹ ti mo da, Jesu! fi ẹjẹ Rẹ wẹ̀ mi, Má ṣai ṣe alagbawi mi.
p ‘Gba gbogbo iṣẹ ọjọ pin, Ti ara si nfẹ lọ simi, F’ anu t’ o kun fun ‘dariji, Dabobò mi, Oluwa mi; Bi orùn si ti ‘ma goke, Bẹni k’o gb’ ero mi soke.
p ‘Gbat’ orùn aíye mi ba wọ̀, Ti kò si si wahala mọ, Jẹ k’imọlẹ tirẹ, Jesu! Tan boji ti mo sùn yika; f Gb’ ẹmi mi dide, Oluwa, Ki nri Ọ, ki nsì gbe Ọ ga. Amin.