- mf Mo f’ẹmi mi sabẹ
Itọju Rẹ Jesu;
‘Wọ kò jọ mi l’ ainireti,
‘Wọ l’ Ọlọrun Ifẹ.
- f ‘Wọ ni mo gbẹkẹle,
‘Wọ ni mo f’ara tì;
Rere at’ Otitọ ni Ọ,
Eyi t’ O ṣe l’ o tọ́.
- Ohun t’o wù k’o de,
Ifẹ Rẹ ni nwọn nṣe:
p Mo f’ ori pamọ saiya Rẹ,
Nkò foìya ìji yi.
- f B’ ibi tab’ ire de,
Y’o dara fun mi ṣa !
Ki nsa ni Ọ l’ ohun gbogbo,
Ohun gbogbo n’nu Rẹ. Amin.