- mp Alafia, li aiye ẹ̀ṣẹ yi?
Ẹjẹ Jesu nwipe, “Alafia.”
- mf Alafia, ninu ọpọ lala?
Lati ṣe ifẹ Jesu, ni ‘simi.
- Alafia, n’nu ìgbi banujẹ?
L’aiya Jesu ni dakẹ rọrọ wà.
- mp Alafia, gb’ ará wa wà l’ajo?
Ni ‘pamọ Jesu, ibẹru kò si.
- f Alafia, b’ a kò tilẹ m’ ọla?
Ṣugbon a mọ̀ pe Jesu wà lailai.
- mp Alafia, nigb’ akoko ikú?
f Olugbala wa ti ṣẹgun ikú
- di O tó: jakadi aiye fẹrẹ pin,
p Jesu y’o pe wa s’ ọrun alafia. Amin.