- F’ ẹ̀ru rẹ f’ afẹfẹ,
N’ ireti má fòya;
Ọlọrun gbọ́ ‘mikanlẹ̀ rẹ,
Yio gb’ ori rẹ ga.
- N’ irumi at’ iji,
Y’o ṣ’ ọna rẹ fefe:
Duro de ìgba Rẹ̀; òru
Y’o pin s’ọjọ ayọ̀.
- Iwọ r’ ailera wa,
Inu wa n’ iwọ mọ̀’
Gbe ọwọ t’ o rẹ̀ si òke,
M’ ekun ailera le.
- K’ awa n’ ìye n’ikú,
Sọ ọ̀rọ Rẹ tantan;
K’ a sọ tit’ opin ẹmi wa,
Ifẹ, itọju Rẹ. Amin.