- mp Nihin mo j’ alejo,
Ọrun n’ile.
Atipo ni mo nṣe,
Ọrun n’ ile.
Ewu on banujẹ
Wà yi mi kakiri;
cr Ọrun ni ìlu mi,
Ọrun n’ile.
- mf B’ ijì ba tilẹ̀ njà,
Ọrun n’ile.
di Kukuru l’ajo mi,
Ọrun n’ile.
Ijì lile ti njà,
cr Fẹ rekọja lọ na;
Ngo sa de ‘le dandan,
f Ọrun n’ile.
- mf Lọdọ Olugbala,
Ọrun n’ile.
cr A o ṣe mi logo,
Ọrun n’ile.
p Nib’ awọn mimọ wà,
Lẹhin ‘rìn-àjo wọn,
Ti nwọn ni ‘simi wọn,
cr Nibẹ n’ile.
- mf Njẹ nkì o kùn, tori
Ọrun n’ile.
Ohun t’o wù ki nri,
Ọrun n’ile.
cr Ngo sa duro dandan,
L’ọtún Oluwa mi:
ff Ọrun ni ilu mi
Ọrun n’ile. Amin.