Hymn 388: Rescue the perishing, care for the dying

Yo awon ti nsegbe, sajo eni nku

  1. mf Yọ awọn ti nṣègbe, ṣajò ẹni nkú,
    cr F’anu já wọn kuro ninu ẹṣẹ,
    Ké f’awọn ti nṣìna, gb’ ẹni ṣubu ró,
    Sọ fun wọn pe, Jesu le gbà wọn là.
    p Yọ awọn ti nṣègbe, ṣajo ẹni nku,
    cr Alanu ni Jesu, yio gbàla.

  2. mf Bi nwọn o tilẹ gan, sibẹ O nduro
    Lati gb’ọmọ t’o ronupiwada;
    p Sa f’ itara rọ̀ wọn, si rọ̀ wọn jẹjẹ,
    On o dariji, bi nwọn jẹ gbagbọ.
    p Yọ awọn ti nṣègbe, &c.

  3. mf Yọ awọn ti nṣègbe,--- iṣẹ tirẹ ni;
    Oluwa yio f’agbara fun Ọ;
    Fi suru rọ̀ wọn pada s’ṣna toro;
    Sọ f’aṣako p’Olugbala ti ku.
    p Yọ awọn ti nṣègbe, ṣajo ẹni nku,
    Alanu ni Jesu, yio gbàla. Amin.