- f Ẹmi Ọlọrun alaye,
N’nu ẹkún ore-ọfẹ Rẹ,
Nibit’ ẹsẹ enia ti tẹ,
Sọkalẹ sori iran wa.
- F’ẹbun ahọn, ọkan ife,
Fun wa lati sọrọ ‘fẹ Re,
Bà l’awọn t’o ngbọ́ ọ̀rọ na.
- K’okùn kàsẹ̀ ni bibọ̀ Rẹ:
Ki dàrudàpọ di titọ́;
F’ ilera f’ọkàn ailera;
Jẹ ki anu bori ‘binu.
- mp Ẹmi Ọlọrun, jọ pèsè
Gbogbo aiye fun Oluwa:
cr Mí si wọn b’ afẹfẹ orọ̀,
K’ ọkàn okuta le sọji.
- f Baptis’ gbogb’ orilẹ-ede;
Rohin ‘ṣẹgun Jesu yika;
Yin orukọ Jesu logo
Tit’ araiye yio jẹwọ Rẹ̀. Amin.