Hymn 403: What means this eager, anxious throng

Eredi irokeke yi

  1. f Eredi irọ́kẹ̀kẹ yi
    Ti enia ti nwọ koja?
    ‘Jojumọ n’iwọjọpọ na,
    Eredi rẹ̀ ti nwọn nṣe bẹ?
    f Nwọn dahùn lohun jẹjẹ pe,
    di “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
    f Nwọn dahùn lohun jẹjẹ pe,
    di “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”

  2. mf Tani Jesu? Eṣe ti On
    Fi nmì gbogbo ilu bayi?
    Ajeji Ọlọgbọn ni bi,
    Ti gbogb’ enia ntọ lẹhin?
    p Nwọn si tun dahun jẹjẹ pe,
    cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
    p Nwọn si tun dahun jẹjẹ pe,
    cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”

  3. Jesu, On na l’O ti kọja,
    p Ọna irora wa laiye;
    ‘Bikibi t’O ba de, nwọn nkò
    Oriṣi àrun wa ‘dọ̀ Rẹ̀;
    f Afọju yọ̀, b’o ti gbọ pe,
    cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
    f Afọju yọ̀, b’o ti gbọ pe,
    cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”

  4. On sì tun de! nibikibi
    Ni awa si nri ‘pasẹ̀ Rẹ̀:
    O nrekọja lojude wa----
    O wọle lati ba wa gbe.
    f Kò ha yẹ k’a f’ayọ̀ ke pe?
    cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
    f Kò ha yẹ k’a f’ayọ̀ ke pe?
    cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”

  5. Ha ! ẹ wá enyin t’ọrùn nwọ̀!
    f Gbà ‘dariji at’ ìtunu:
    p Ẹnyin ti ẹ ti ṣako lọ,
    cr Pada, gbà or-ọfẹ Baba;
    Ẹnyin t’a danwò, abò mbẹ,
    f “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
    Ẹnyin t’a danwò, abò mbẹ,
    f “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”

  6. p Ṣugbọn b’iwọ kọ̀ ipè yi,
    cr Ti o sì gàn ifẹ nla Rẹ̀,
    On yio kẹ̀hinda si ọ,
    Yio si kọ̀ adurà rẹ;
    p “O pẹ ju” n’ igbe na y’o jẹ:---
    pp “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
    p “O pẹ ju” n’ igbe na y’o jẹ:---
    pp “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.” Amin.