Hymn 41: PRAISE, O praise our God and King;

Yin Olorun Oba wa

  1. f Yin Ọlorun Ọba wa;
    Ẹ gbe ohun iyin ga;
    Anu Rẹ̀ o wa titi
    Lododo dajudaju.

  2. mf Yin Ẹnit’ o da orùn
    Ti o nràn lojojumo;
    f Anu Rẹ̀ o wa titi
    Lododo dajudaju.

  3. Ati oṣupa loru
    Ti o ntanmọlẹ jẹjẹ;
    f Anu Rẹ̀ o wa titi
    Lododo dajudaju.

  4. mf Yin Ẹnit’ o nm’ojò rọ̀
    T’ o nmu irugbin dagba
    f Anu Rẹ̀ o wa titi
    Lododo dajudaju.

  5. mf Ẹnit’ o paṣẹ fun ‘lẹ
    Lati mu eso pò sí;
    f Anu Rẹ̀ o wa titi
    Lododo dajudaju.

  6. f Yin fun ikore oko,
    O mu ki àká wa kun;
    f Anu Rẹ̀ o wa titi
    Lododo dajudaju.

  7. mp Yin f’onjẹ t’ o jù yi lọ,
    Ẹri ‘bukun ailopin;
    f Anu Rẹ̀ o wa titi
    Lododo dajudaju.

  8. un Ogo f’Ọba olore:
    Ki gbogbo ẹda gberin:
    Ogo fun Baba, Ọmọ,
    At’ Emi: Metalọkan. Amin.