Hymn 418: We adore Thee O Lord.

Awa f’ ori bale fun

  1. mf Awa f’ori balẹ fun | Ọ Jesu,
    ‘Wọ ti ṣ’ Olori Ijọ awọn | enia Rẹ,
    Ijọ ti mbẹ laiye yi, ati lọ|run pẹlu:
    Alle|luya !

  2. p ‘Wọ t’o ku, t’o sì jin|de fun wa,
    T’o mbẹ lọdọ Baba bi Ala|gbawi wa,
    K’ogo at’ọlanla | jẹ Tirẹ:
    Alle|luya !

  3. mf Ati li ọjọ nla Pẹn | tikọsti,
    Ti o ran Parakliti | si aiye,
    Olutun nla Rẹ ti | mba wa gbe:
    Alle|luya !

  4. f Lat’ ori itẹ Rẹ l’ o|ke ọrun,
    L’O si nwò gbogbo awọn o|jiṣẹ Rẹ,
    T’O si nṣikẹ gbogbo awọn Ajẹ|riku Rẹ:
    Alle|luya !

  5. f A fi iyìn at’ ọlanla f’ o|rukọ Rẹ,
    p N’tori iku gbogbo awọn o|jiṣẹ Rẹ,
    Ni gbogbo ilẹ Yo|ruba yi:
    Alle|luya ! Amin.