Hymn 444: Till he come, O let the words

‘K’ On to de, - je k’oro yi

  1. cr ‘K’ On tó de, ‘---jẹ k’ọ̀rọ yi
    Ma dún titi l’eti rẹ;
    Jẹ ki sa diẹ t’o kù
    Hàn gbangba daju fun ọ;
    f Ronu b’ọrun on ile
    di Ti d‘ẹ̀hin gbat’ ‘O ba de.’

  2. p Gbat’ awọn ti a fẹràn
    Bọ́ si ‘simi wọn l’oke,
    T’o jọ pe aiye wa pin,
    Ti adùn rẹ̀ si korò;
    di Ẹ dakun, ẹ má b’ọhun,
    cr Kiki ‘k’ On to de’ ṣá ni.

  3. mp Ibanujẹ yi wa ka;
    A ha fẹ k’o dinku bi?
    Gbogbo ẹrù ipọnju,
    Gbogbo òfo aiye yi,
    Iku, ọ̀fọ aiye yi,
    p Nsọ jẹjẹ pe, ‘K’ On t’o de.’

  4. mf Wo tabil’ ifẹ t’a tẹ́,
    Mu waini, si j’akara;
    ‘Ranti didun, ---k’ Oluwa
    To pè wa s’onjẹ ọrun;
    p ‘Mì kat’ aiye, ‘m’ l’ọrun,
    cr Nwọn pinyà tit’ ‘On fi de.´ Amin.