- mf Jesu fẹ mi, mo mọ̀ bẹ,
Bibeli l’o sọ fun mi;
Tirẹ l’awọn ọmọde,
p.f Nwọn kò lagbara, On ni.
- p Jesu fẹ mi, Ẹn’ t’o kú
Lati ṣi ọrun silẹ;
mf Yio wẹ̀ ẹ̀ṣẹ mi nù:
Jẹki ọmọ Rẹ̀ wọle.
- p Jesu fẹ mi sibẹ si,
Bi emi tilẹe ṣ’aìsàn
cr Lor’ akete aisan mi,
Yio t’itẹ Rẹ̀ wá ṣọ́ mi.
- mf Jesu fẹ mi, y’o duro
Ti mi ni gbogb’ ọna mi,
Gba mba f’aiye yi silẹ̀,
Y’o mu mi re ‘le ọrun. Amin.