mf Gbat’ O ba de, gbat’ O ba de, Lati ṣir` ọ̀ṣọ́ Rẹ̀; Gbogb’ ọ̀ṣọ́ Rẹ̀ iyebiye, Awọn ti O fẹ! f Bi ìrawọ owurọ, nwọn nṣ’ade Rẹ̀ lọṣọ, Ẹwà wọn o yọ pupọ̀, ẹwà f’ade Rẹ̀.
Yio kójọ, yio kójọ, Ọṣọ́ ijọba Rẹ̀; Awọn mimọ, awọn dídán, Awọn ti O fẹ. f Bi irawọ, &c.
Awọn ewe, awọn ewe T’o fẹ Olugbala; Ni ọ̀ṣọ́ Rẹ̀ iyebiye, Awọn ti Ò fẹ. f Bi ìrawọ owurọ, nwọn nṣ’ade Rẹ̀ lọṣọ, Ẹwà wọn o yọ pupọ̀, ẹwà f’ade Rẹ̀. Amin.