- f Ọlọrun, orin ẹniti
Awọn Angẹli nkọ;
Wò ‘lẹ̀ lati bujoko Rẹ!
Kọ wa, k’a bẹ̀ru Rẹ!
- Ọrọ mimọ́ Rẹ l’ a fẹ kọ́,
Lat’ igba ewe wa;
K’ a kọ t’ Olugbala t’ iṣe
Ọna, Iye, Otọ.
- Jesu, ogo at’ ore Rẹe,
L’ a nsọ nisisiyi;
Ṣe bujoko Rẹ s’ ọkàn wa,
Si jẹ k’ a bẹ̀ru Rẹ. Amin.