Hymn 49: Thou art coming, O my Saviour,

Iwo mbo wa, Oluwa mi

  1. f Iwọ mbọ̀ wá, Oluwa mi,
    Iwọ bọ wá, Ọba mi,
    cr Ninu ìtansan ẹ̀wa Rẹ;
    Ninu titayọ ogo Rẹ;
    O yẹ k’a yọ̀, k’a kọrin !
    p.cr O mbọ̀; -- ni ìla-orun
    Awọn akede npọ̀ si;
    p.cr O mbọ̀: -- Alufa ogo;
    A ko ha ngbọ ago Rẹ?

  2. f Iwọ mbọ̀ wá, Iwọ mbọ̀ wá
    A o pade Rẹ lọnà;
    cr A o ri Ọ, a o mọ̀ Ọ,
    A o yin Ọ; gbogbo ọkàn
    L’a o ṣipaya fun Ọ:
    f Orin kil’ eyi o jẹ!
    Orin t’o dùn rekọja:
    A o tu ‘fẹ wa jade
    Si ẹsẹ̀ Rẹ Ologo.

  3. mf Iwo mbọ wà; ni tabil’ Rẹ,
    L’ awa njeri si eyi;
    p T’a mọ̀ p’ O npade ọkàn wa
    Ni ìdapọ mimọ́ julọ;
    Ẹri ibukun ti mbọ,
    cr Kò f’ iku Rẹ nikan hàn,
    At’ ifẹ titobi Rẹ,
    Ṣugbọn bibò Rẹ pẹlu
    T’a nfẹ, t’a si nduro dè.

  4. f Y’o dùn lati ri Ọ njọba
    Oluwa mi Olufẹ;
    cr Ki gbogbo ahọn jẹwọ Rẹ;
    Iyin, ọla, ati ogo,
    Ki nwọn jumọ fi fun Ọ:
    ff ‘Wọ, Ọga mi, Ọrẹ mi,
    K’o ṣẹgun, k’ o si gunwa,
    Titi de opin aiye,
    Ninu ogo at’ ọla. Amin.