- mf K’ awa to pari ẹkọ wa,
Awa f’ iyin fun Ọ;
‘Tori ọjọ Rẹ mimọ́ yi,
Jesu, Ọrẹ́ ewe.
- f Gbin ọ̀rọ Rẹ si ọkàn wa,
Gbà wa lọwọ ẹ̀ṣẹ;
Má jẹ k’ a pada lẹhin Rẹ,
Jesu, Ọrẹ́ ewe.
- Jesu jọ bukun ile wa;
K’ a lò ọjọ yi ‘re;
K’ a le ri àye l’ ọdọ Rẹ,
Jesu, Ọrẹ́ ewe. Amin.