- mf Ire t’ a sú ni Eden,
N’ igbeyawo ‘kini,
Ibukun t’ a bukun wọn,
O wà sibẹ̀ sibẹ̀.
- Sibẹ titi di oni,
N’ igbeyawo Kristian,
Ọlọrun wà larin wa,
Lati sure fun wa.
- Ire ki nwọn lè ma bi,
Ki nwọn k’o sì ma rẹ̀;
Ki nwọn ni dapọ mimọ́,
T’ ẹnikan k’yo le tú.
- p Ba ni pé, Baba, si fà
cr Obinrin yi f’ ọkọ;
Bi O ti fi Efa fun
Adam lọjọ kini.
- p Ba wa pé Immanucli,
cr Si so ọwọ wọn pọ̀,
B’ ẹda meji ti papọ̀
L’ ara ìjinlẹ Rẹ.
- p Ba wa pé, Ẹmi Mimọ́,
cr F’ ibukun Rẹ fun wọn:
Si ṣe wọn ni aṣepé,
Gẹgẹ b’ O ti ma ṣe.
- mf Fi nwọn abẹ abò Rẹ,
K’ ibi kan má ba wọn;
‘Gba nwọn nparà ile Rẹ,
Ma tọju ọkàn wọn.
- cr Pẹlu wọn, l’ ọj’ aiye wọn,
At’ ọkọ at’ aya;
f Titi nwọn o de ọdọ Rẹ,
N’ ile ayọ̀ l’ ọrun. Amin.