mf Sọ ìtan kanna fun mi, T’ ohun nì t’a kò ri; cr Ti Jesu on ogo Rẹ̀, Ti Jesu on ‘fẹ Rẹ, mp Sọ ìtan kanna fun mi, B’o ba ti sṣ f’ ewe, ‘Tor’ alailera l’ewe, Emi kò si n’ okun. Sọ ìtan kanna fun mi, Sọ ìtan kanna fun mi, Sọ ìtan kanna fun mi, Ti Jesu on ‘fẹ Rẹ̀.
Sọ ‘tàn na fun mi pẹ̀lẹ́, Ki o ba le ye mi; T’ irapada iyanu, T’ etutu fun ẹ̀ṣẹ; Sọ fun mi nìgbagbogbo, ‘Tori nkò pẹ gbagbe; di Oye ori mi ti lọ, Bi irì owurọ. Sọ ìtan kanna fun mi, &c.
mf Sọ ‘tan kanna fun mi jẹjẹ, Li ohùn otitọ: Ranti p’ ẹlẹṣẹ l’ emi, Ti Jesu wá gbala, Sọ fun mi, nigbakugba, Bi iwọ ba fẹ ṣe Olutunu mi n’ igba Ọjọ ibi ba de. Sọ ìtan kanna fun mi, &c.
Sọ itàn kanna fun mi, Igba ti o ba ri Pe ogo aiye wa yi Fẹ gba mi li aiya: cr ‘Gba ogo oke ọrun, Ba si nfarahan mi; f Sọ ‘tàn kanna fun mi pe, Krist mu ọ l’ ara da. Sọ ìtan kanna fun mi, &c. Amin.