- mp Ọna Rẹ, Oluwa,
B’o ti wù k’o dí to,
Fi ọwọ Rẹ tọ́ mi,
Yàn ipa mi fun mi.
- p B’o rọrùn, b’o ṣoro,
Daradara l’o jẹ;
B’o run tab’ o wọ́ ni,
Dandan s’isimi ni.
- Nkò gbọdọ yàn ‘pín mi,
Nko tilẹ jẹ́ yàn a;
Yan fun mi, Ọlọrun,
Bẹni ngo rìn dede.
- Ijọba t’emi nwá,
Tirẹ ni; jẹ k’ọna
T’o re ‘bẹ̀ jẹ Tirẹ;
Bi bẹkọ ngo nṣìna.
- p Gbà ago mi, fayọ̀
cr Tab’ ibanujẹ kun;
B’o ti tọ́ l’oju Rẹ,
Yàn ‘re tab’ ibi mi.
- Yàn ọrẹ́ mi fun mi,
p Aìsan tab’ ilera;
Yàn aniyan fun mi,
Aini tabi ọrọ̀.
- Yiyàn k’ iṣe t’emi,
Ninu ohunkohun;
Iwọ ṣ’olutọ mi,
Ọgbọn on gbogbo mi. Amin.