Hymn 513: Hark the divine voice from on high

Gb’ ohun t’o t’ orun wa ti wi

  1. mp Gb’ ohùn t’o t’ ọrun wá ti wi,
    cr F’ awọn okú mimọ́;
    Didun n’ irant’ orukọ wọn,
    ‘Busùn wọn n’ itura.

  2. Nwọn kú n’nu Jesu àbukún,
    Orun wọn ti dùn to!
    p Ninu irora on ẹ̀ṣẹ,
    Nwọn yọ ninu ‘danwo.

  3. Lọnà jijin s’aiye iṣẹ́,
    Nwọn mbẹ lọd’ Oluwa;
    f Iṣẹ wọn l’aiye ikú yi,
    di Pari li eré nla. Amin.