- mf Ọlọrun, lat’orọ̀ d’alẹ,
Wakati wo l’o dùn pupọ̀,
B’ eyi t’o pè mi wadọ Rẹ
Fun adura?
- Ibukun n’itura orọ̀;
Ibukun sì l’oju ale;
Gbati mo f’ adura gòke
Kuro laiye !
- ‘Gbana ‘mọlẹ kan mọ́ si mi,
O dán jù ‘mọlẹ orùn lọ;
Iri ‘bukun t’aiye kò mọ̀,
T’ ọ̀dọ Rẹ wá.
- Gbana l’ agbara mì dọtun,
Gbana l’a f’ẹṣẹ mi jì mi.
Gbana l’o f’ ireti ọrun
M’ara mi yá.
- Ẹnu kò le sọ ibukun
Ti mo nrí f’ aini mi gbogbo;
Agbara, itunu, ati
Alafia.
- Ẹrù at`iyemeji tán,
Ọkàn mi f’ọrun ṣe ile;
Omije ‘ronupìwada
L’a nù kurò.
- Titi ngo de ‘lẹ ‘bukun na,
Kò s’ anfani t’o le dùn, bi
Ki nma tú ọkàn mi fun Ọ
Nin’ adura ! Amin.