f Wakati adurà didùn! T’o gbe mi lọ kuro laiye, L’ọ ‘waju itẹ Baba mi, Ki nsọ gbogbo ẹ̀dun m fun; cr Nigba ‘banujẹ at’ arò, Adua l’ abò fun ọkàn mi; Emi si bọ̀ lọwọ Eṣu, ‘Gbati mo ba gb’ adua didùn, Emi si bọ́ lọwọ Eṣu, ‘Gbati mo ba gb’ adua didun.
f Wakati adurà didùn ! Iyẹ rẹ y’o gbe ẹ̀bẹ mi Lọ sọd’ Ẹnit’ o ṣeleri Lati bukun ọkàn adua: B’ O ti kọ́ mi, ki nw’ oju Rẹ̀, Ki ngbẹkẹle, ki nsi gba gbọ: Ngo kó gbogb` aniyan mi le, Ni akoko adua didùn. Ngo kó gbogb` aniyan mi le, Ni akoko adua didùn.
Wakati adurà didùn ! Jẹ ki nma r’itunu rẹ gbà, Titi ngo fi d’oke Pisga, Ti ngo r’ile mi l’okere. Ngo bọ́ agọ ara silẹ, Ngo gbà ère ainipẹkun; f Ngo kọrin bi mo ti nfò lọ, cr Odigboṣe ! adua didùn. f Ngo kọrin bi mo ti nfò lọ, cr Odigboṣe ! adua didùn. Amin.