- mf Jẹ ki ilekun aitase,
Ṣi fun iṣẹ wa, Oluwa,
Ti o ṣi ti kì o tì mọ,
Ilẹkun ‘wọle ọ̀rọ Rẹ.
- f F’ ọwọ iná tọ ète wọn,
Fi nfi ‘lanà Rẹ hàn aiye;
F’ ifẹ mimọ́ si aiya wọn,
Ti Ọlọrun at’enia.
- F’ itara fun iranṣẹ Rẹ,
T’ ohun kan kò lè mu tutu;
Bi nwọn si ti ntàn ọ̀rọ Rẹ,
Bukun ìmọ at’ iṣẹ wọn.
- Ran Ẹmi Rẹ lat’ oke wá,
Ma’ jẹ ki agbara Rẹ̀ pin:
Tit’ irira o fi pari,
Ti gbogbo ija o si tan. Amin.