- mf Ọlọrun, a sọ ọ̀rọ Rẹ,
Bi ‘rugin l’or’ilẹ;
Jẹ k’ ìri ọrun sẹ̀ silẹ̀,
K’o mu ipa Rẹ wa.
- K’ọta Kristi on enia,
Má ṣe ṣa ‘rugbin nà;
K’o f’ irìn mulẹ̀ l’ọkàn wa,
K’o dagba ni ifẹ.
- cr Má jẹ ki aniyan aiye,
Bi ọrọ̀ on ayọ̀,
Tabi ijona, on ìji,
Run irugbin ọrun. Amin.