- f Ji ! kọ orin Mose
Ati t’Ọd’agutan;
Ji gbogbo ọkàn at’ ahọn,
Ki nwọn yin Oluwa.
- p Kọrin ti ikù rẹ̀,
f Kọrin ajinde Rẹ̀;
cr Kọrin b’ O ti mbẹbẹ loke,
F’ ẹ̀ṣẹ awọn t’O rù.
- mf Ẹnyin èro l’ọnà,
Ẹ kọrin b’ ẹ ti nlọ;
ff Ẹ yọ̀ ninu Ọdagutan,
Ninu Kristi Ọba.
- Ẹ fẹ gbọ k’O wipe,
“Alabukun, ẹ wá”
On fẹrẹ̀ pè nyin lọ kurò,
K’O mu Tirẹ̀ lọ ‘le.
- cr Nibẹ l’a o kọrin
Iyìn Rẹ̀ ailopin,
f Ọrun y’o si gbe ‘rin Mose,
Ati t’Ọd’agutan. Amin.