- f Niwaju itẹ Jehofa,
Ẹ f’ayọ̀ sìn, oril’ ede;
Mọ p’ Oluwa, on kanṣo ni,
O le dá, O si lè parun.
- mf Ipa Rẹ̀, laisi ranwọ wa,
F’ amọ̀ dá wa ni enia;
p Nigba t’a ṣako b’agutan,
cr O tun wa mu’ si agbo Rẹ̀.
- ff A o f’ orin sunmọ ‘le Rẹ,
Lohùn giga l’a o kọrin;
Ilẹ, l’ ẹgbarun ahọn rẹ̀,
Y’o f’ iyin kún agbala Rẹ.
- Aṣẹ Rẹ gboro b’agbaiye,
Ifẹ Rẹ pọ̀ b’aiyeraiye;
Ọtọ Rẹ y’o duro lailai,
‘Gbat’ọdun o dẹkun ‘yipo. Amin.